Joẹli 3:10
Joel 3:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ fi irin ìtulẹ̀ yín rọ idà, àti dòjé yín rọ ọ̀kọ̀. Jẹ́ kí aláìlera wí pé, “Ara mi le koko.”
Joel 3:10 in English
Joel 3:10 · Berean Standard Bible
Beat your plowshares into swords and your pruning hooks into spears. Let the weak say, ‘I am strong!’
Context
8Èmi yóò si tà àwọn ọmọkùnrin yín àti àwọn ọmọbìnrin yín sí ọwọ́ àwọn ọmọ Juda, wọ́n yóò sì tà wọ́n fún àwọn ara Sabeani, fún orílẹ̀-èdè kan tí ó jìnnà réré.” Nítorí Olúwa ní o ti sọ ọ. 9Ẹ kéde èyí ní àárín àwọn kèfèrí;
ẹ dira ogun,
ẹ jí àwọn alágbára.
Jẹ kí àwọn ajagun kí wọn bẹ̀rẹ̀ ogun. 10Ẹ fi irin ìtulẹ̀ yín rọ idà,
àti dòjé yín rọ ọ̀kọ̀.
Jẹ́ kí aláìlera wí pé,
“Ara mi le koko.” 11Ẹ wá kánkán, gbogbo ẹ̀yin kèfèrí láti gbogbo àyíká,
kí ẹ sì gbá ara yín jọ yí káàkiri.
Níbẹ̀ ní kí o mú àwọn alágbára rẹ sọ̀kalẹ̀, Olúwa. 12“Ẹ jí, ẹ sì gòkè wá sí àfonífojì
Jehoṣafati ẹ̀yin kèfèrí:
nítorí níbẹ̀ ní èmi yóò jókòó láti ṣe
ìdájọ́ àwọn kèfèrí yí káàkiri.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.