Joẹli 3:11
Joel 3:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ wá kánkán, gbogbo ẹ̀yin kèfèrí láti gbogbo àyíká, kí ẹ sì gbá ara yín jọ yí káàkiri. Níbẹ̀ ní kí o mú àwọn alágbára rẹ sọ̀kalẹ̀, Olúwa.
Joel 3:11 in English
Joel 3:11 · Berean Standard Bible
Come quickly, all you surrounding nations, and gather yourselves. Bring down Your mighty ones, O LORD.
Context
9Ẹ kéde èyí ní àárín àwọn kèfèrí;
ẹ dira ogun,
ẹ jí àwọn alágbára.
Jẹ kí àwọn ajagun kí wọn bẹ̀rẹ̀ ogun. 10Ẹ fi irin ìtulẹ̀ yín rọ idà,
àti dòjé yín rọ ọ̀kọ̀.
Jẹ́ kí aláìlera wí pé,
“Ara mi le koko.” 11Ẹ wá kánkán, gbogbo ẹ̀yin kèfèrí láti gbogbo àyíká,
kí ẹ sì gbá ara yín jọ yí káàkiri.
Níbẹ̀ ní kí o mú àwọn alágbára rẹ sọ̀kalẹ̀, Olúwa. 12“Ẹ jí, ẹ sì gòkè wá sí àfonífojì
Jehoṣafati ẹ̀yin kèfèrí:
nítorí níbẹ̀ ní èmi yóò jókòó láti ṣe
ìdájọ́ àwọn kèfèrí yí káàkiri. 13Ẹ tẹ dòjé bọ̀ ọ́,
nítorí ìkórè pọ́n.
Ẹ wá, ẹ sọ̀kalẹ̀,
nítorí ìfúntí kún,
nítorí àwọn ọpọ́n kún àkúnwọ́sílẹ̀,
nítorí ìwà búburú wọn pọ̀!”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.