Joẹli 3:8
Joel 3:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi yóò si tà àwọn ọmọkùnrin yín àti àwọn ọmọbìnrin yín sí ọwọ́ àwọn ọmọ Juda, wọ́n yóò sì tà wọ́n fún àwọn ara Sabeani, fún orílẹ̀-èdè kan tí ó jìnnà réré.” Nítorí Olúwa ní o ti sọ ọ.
Joel 3:8 in English
Joel 3:8 · Berean Standard Bible
I will sell your sons and daughters into the hands of the people of Judah, and they will sell them to the Sabeans—to a distant nation.” Indeed, the LORD has spoken.
Context
6Àti àwọn ọmọ Juda, àti àwọn ọmọ Jerusalẹmu ní ẹ̀yin ti tà fún àwọn ará Giriki, kí ẹ̀yin bá à lè sí wọn jìnnà kúrò ní agbègbè ilẹ̀ ìní wọn. 7“Kíyèsi í, èmi yóò gbé wọ́n dìde kúrò níbi tì ẹ̀yin ti tà wọ́n sí, èmi yóò sì san ẹ̀san ohun ti ẹ ṣe padà sórí ara yín. 8Èmi yóò si tà àwọn ọmọkùnrin yín àti àwọn ọmọbìnrin yín sí ọwọ́ àwọn ọmọ Juda, wọ́n yóò sì tà wọ́n fún àwọn ara Sabeani, fún orílẹ̀-èdè kan tí ó jìnnà réré.” Nítorí Olúwa ní o ti sọ ọ. 9Ẹ kéde èyí ní àárín àwọn kèfèrí;
ẹ dira ogun,
ẹ jí àwọn alágbára.
Jẹ kí àwọn ajagun kí wọn bẹ̀rẹ̀ ogun. 10Ẹ fi irin ìtulẹ̀ yín rọ idà,
àti dòjé yín rọ ọ̀kọ̀.
Jẹ́ kí aláìlera wí pé,
“Ara mi le koko.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.