Joẹli 2:28
Joel 2:28 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Yóò sì ṣe níkẹyìn ọjọ́, èmi yóò tú nínú Ẹ̀mí mí sí ara ènìyàn gbogbo; àwọn ọmọ yín ọkùnrin àti àwọn ọmọ yín obìnrin yóò máa sọtẹ́lẹ̀, àwọn arúgbó yín yóò máa lá àlá, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yín yóò máa ríran.
Joel 2:28 in English
Joel 2:28 · Berean Standard Bible
And afterward, I will pour out My Spirit on all people. Your sons and daughters will prophesy, your old men will dream dreams, your young men will see visions.
Context
26Ẹ̀yin yóò ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ láti jẹ, títí ẹ̀yin yóò fi yó
ẹ ó sì yín orúkọ Olúwa Ọlọ́run yín,
ẹni tí ó fi ìyanu bá yín lò;
ojú kì yóò sì ti àwọn ènìyàn mi láéláé. 27Ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, èmi wà láàrín Israẹli,
àti pé; Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín,
àti pé kò sí ẹlòmíràn,
ojú kì yóò sì ti àwọn ènìyàn mí láéláé. 28“Yóò sì ṣe níkẹyìn ọjọ́,
èmi yóò tú nínú Ẹ̀mí mí sí ara ènìyàn gbogbo;
àwọn ọmọ yín ọkùnrin àti àwọn ọmọ yín obìnrin yóò máa sọtẹ́lẹ̀,
àwọn arúgbó yín yóò máa lá àlá,
àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yín yóò máa ríran. 29Àti pẹ̀lú sí ara àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ ọkùnrin,
àti sí ara àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ obìnrin,
ní èmi yóò tú ẹ̀mí mí jáde ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì. 30Èmi yóò sì fi iṣẹ́ ìyanu hàn ní ọrun
àti ní ayé,
ẹ̀jẹ̀ àti iná, àti ọ̀wọ́n èéfín.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.