Native Bible

Joel 2:27 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, èmi wà láàrín Israẹli, àti pé; Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín, àti pé kò sí ẹlòmíràn, ojú kì yóò sì ti àwọn ènìyàn mí láéláé.

Joel 2:27 in English

Joel 2:27 · Berean Standard Bible

Then you will know that I am present in Israel and that I am the LORD your God, and there is no other. My people will never again be put to shame.

Context

25“Èmi yóò sì mú ọdún wọ̀nyí ti eṣú jẹ run padà fún un yín. Èyí tí eṣú agénijẹ àti eṣú jewéjewé ọwọ́ eṣú agénijẹ àti kòkòrò ajẹnirun mìíràn ti fi jẹ àwọn ogun ńlá mi tí mo rán sí àárín yín. 26Ẹ̀yin yóò ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ láti jẹ, títí ẹ̀yin yóò fi yó ẹ ó sì yín orúkọ Olúwa Ọlọ́run yín, ẹni tí ó fi ìyanu bá yín lò; ojú kì yóò sì ti àwọn ènìyàn mi láéláé. 27Ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, èmi wà láàrín Israẹli, àti pé; Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín, àti pé kò sí ẹlòmíràn, ojú kì yóò sì ti àwọn ènìyàn mí láéláé. 28“Yóò sì ṣe níkẹyìn ọjọ́, èmi yóò tú nínú Ẹ̀mí mí sí ara ènìyàn gbogbo; àwọn ọmọ yín ọkùnrin àti àwọn ọmọ yín obìnrin yóò máa sọtẹ́lẹ̀, àwọn arúgbó yín yóò máa lá àlá, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yín yóò máa ríran. 29Àti pẹ̀lú sí ara àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ ọkùnrin, àti sí ara àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ obìnrin, ní èmi yóò tú ẹ̀mí mí jáde ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.