Joẹli 2:26
Joel 2:26 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ̀yin yóò ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ láti jẹ, títí ẹ̀yin yóò fi yó ẹ ó sì yín orúkọ Olúwa Ọlọ́run yín, ẹni tí ó fi ìyanu bá yín lò; ojú kì yóò sì ti àwọn ènìyàn mi láéláé.
Joel 2:26 in English
Joel 2:26 · Berean Standard Bible
You will have plenty to eat, until you are satisfied. You will praise the name of the LORD your God, who has worked wonders for you. My people will never again be put to shame.
Context
24Àwọn ilẹ̀ ìpakà yóò kún fún ọkà;
àti ọpọ́n wọn nì yóò sàn jáde
pẹ̀lú ọtí wáìnì tuntun àti òróró. 25“Èmi yóò sì mú ọdún wọ̀nyí ti eṣú jẹ run padà fún un yín.
Èyí tí eṣú agénijẹ àti eṣú jewéjewé
ọwọ́ eṣú agénijẹ àti kòkòrò ajẹnirun mìíràn ti fi jẹ
àwọn ogun ńlá mi tí mo rán sí àárín yín. 26Ẹ̀yin yóò ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ láti jẹ, títí ẹ̀yin yóò fi yó
ẹ ó sì yín orúkọ Olúwa Ọlọ́run yín,
ẹni tí ó fi ìyanu bá yín lò;
ojú kì yóò sì ti àwọn ènìyàn mi láéláé. 27Ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, èmi wà láàrín Israẹli,
àti pé; Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín,
àti pé kò sí ẹlòmíràn,
ojú kì yóò sì ti àwọn ènìyàn mí láéláé. 28“Yóò sì ṣe níkẹyìn ọjọ́,
èmi yóò tú nínú Ẹ̀mí mí sí ara ènìyàn gbogbo;
àwọn ọmọ yín ọkùnrin àti àwọn ọmọ yín obìnrin yóò máa sọtẹ́lẹ̀,
àwọn arúgbó yín yóò máa lá àlá,
àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yín yóò máa ríran.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.