Native Bible

Joel 2:30 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi yóò sì fi iṣẹ́ ìyanu hàn ní ọrun àti ní ayé, ẹ̀jẹ̀ àti iná, àti ọ̀wọ́n èéfín.

Joel 2:30 in English

Joel 2:30 · Berean Standard Bible

I will show wonders in the heavens and on the earth, blood and fire and columns * of smoke.

Context

28“Yóò sì ṣe níkẹyìn ọjọ́, èmi yóò tú nínú Ẹ̀mí mí sí ara ènìyàn gbogbo; àwọn ọmọ yín ọkùnrin àti àwọn ọmọ yín obìnrin yóò máa sọtẹ́lẹ̀, àwọn arúgbó yín yóò máa lá àlá, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yín yóò máa ríran. 29Àti pẹ̀lú sí ara àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ ọkùnrin, àti sí ara àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ obìnrin, ní èmi yóò tú ẹ̀mí mí jáde ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì. 30Èmi yóò sì fi iṣẹ́ ìyanu hàn ní ọrun àti ní ayé, ẹ̀jẹ̀ àti iná, àti ọ̀wọ́n èéfín. 31A á sọ oòrùn di òkùnkùn, àti òṣùpá di ẹ̀jẹ̀, kí ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ ẹ̀rù Olúwa tó dé. 32Yóò sí ṣe, ẹnikẹ́ni tí ó ba ké pè orúkọ Olúwa ní a ó gbàlà, nítorí ní òkè Sioni àti ní Jerusalẹmu ní ìgbàlà yóò gbé wà, bí Olúwa ti wí, àti nínú àwọn ìyókù tí Olúwa yóò pè.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.