Joẹli 2:21
Joel 2:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Má bẹ̀rù, ìwọ ilẹ̀; jẹ́ kí inú rẹ̀ dùn kí o sì yọ̀, nítorí Olúwa ti ṣe ohun ńlá.
Joel 2:21 in English
Joel 2:21 · Berean Standard Bible
Do not be afraid, O land; rejoice and be glad, for the LORD has done great things.
Context
19Nítòótọ́, Olúwa yóò dá wọn lóhùn, yóò sì wí fun àwọn ènìyàn rẹ̀ pé:
“Wò ó èmi yóò rán ọkà, àti ọtí wáìnì tuntun, àti òróró sí i yín,
a ó sì fi wọn tẹ́ yín lọ́rùn;
Èmi kì yóò sì fi yín ṣe ẹ̀gàn mọ́
láàrín àwọn aláìkọlà. 20“Ṣùgbọ́n èmi yóò lé ogun àríwá jìnnà réré kúrò lọ́dọ̀ yín,
èmi yóò sì lé e lọ sí ilẹ̀ tí ó ṣá, tí ó sì di ahoro,
pẹ̀lú ojú rẹ̀ sí Òkun ìlà-oòrùn,
àti ẹ̀yìn rẹ̀ sí ìwọ̀-oòrùn Òkun.
Òórùn rẹ̀ yóò sì gòkè,
òórùn búburú rẹ̀ yóò sì gòkè.”
Nítòótọ́ ó ti ṣe ohun ńlá. 21Má bẹ̀rù, ìwọ ilẹ̀;
jẹ́ kí inú rẹ̀ dùn kí o sì yọ̀,
nítorí Olúwa ti ṣe ohun ńlá. 22Ẹ má bẹ̀rù, ẹranko igbó,
nítorí pápá oko aginjù ń rú.
Nítorí igi ń so èso rẹ̀,
igi ọ̀pọ̀tọ́ àti àjàrà ń so èso ọ̀rọ̀ wọn. 23Ẹ jẹ́ kí inú yín dùn, ẹ̀yin ọmọ Sioni,
ẹ sì yọ̀ nínú Olúwa Ọlọ́run yín,
nítorí ó ti fi àkọ́rọ̀ òjò fún yín bí ó ti tọ́,
Òun ti mú kí òjò rọ̀ sílẹ̀ fún un yín,
àkọ́rọ̀ àti àrọ̀kúrò òjò ní oṣù kìn-ín-ní.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.