Native Bible

Joel 2:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ jẹ́ kí inú yín dùn, ẹ̀yin ọmọ Sioni, ẹ sì yọ̀ nínú Olúwa Ọlọ́run yín, nítorí ó ti fi àkọ́rọ̀ òjò fún yín bí ó ti tọ́, Òun ti mú kí òjò rọ̀ sílẹ̀ fún un yín, àkọ́rọ̀ àti àrọ̀kúrò òjò ní oṣù kìn-ín-ní.

Joel 2:23 in English

Joel 2:23 · Berean Standard Bible

Be glad, O children of Zion, and rejoice in the LORD your God, for He has given you the autumn rains for your vindication. He sends you showers, both autumn and spring rains, as before.

Context

21Má bẹ̀rù, ìwọ ilẹ̀; jẹ́ kí inú rẹ̀ dùn kí o sì yọ̀, nítorí Olúwa ti ṣe ohun ńlá. 22Ẹ má bẹ̀rù, ẹranko igbó, nítorí pápá oko aginjù ń rú. Nítorí igi ń so èso rẹ̀, igi ọ̀pọ̀tọ́ àti àjàrà ń so èso ọ̀rọ̀ wọn. 23Ẹ jẹ́ kí inú yín dùn, ẹ̀yin ọmọ Sioni, ẹ sì yọ̀ nínú Olúwa Ọlọ́run yín, nítorí ó ti fi àkọ́rọ̀ òjò fún yín bí ó ti tọ́, Òun ti mú kí òjò rọ̀ sílẹ̀ fún un yín, àkọ́rọ̀ àti àrọ̀kúrò òjò ní oṣù kìn-ín-ní. 24Àwọn ilẹ̀ ìpakà yóò kún fún ọkà; àti ọpọ́n wọn nì yóò sàn jáde pẹ̀lú ọtí wáìnì tuntun àti òróró. 25“Èmi yóò sì mú ọdún wọ̀nyí ti eṣú jẹ run padà fún un yín. Èyí tí eṣú agénijẹ àti eṣú jewéjewé ọwọ́ eṣú agénijẹ àti kòkòrò ajẹnirun mìíràn ti fi jẹ àwọn ogun ńlá mi tí mo rán sí àárín yín.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.