Joẹli 2:19
Joel 2:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítòótọ́, Olúwa yóò dá wọn lóhùn, yóò sì wí fun àwọn ènìyàn rẹ̀ pé: “Wò ó èmi yóò rán ọkà, àti ọtí wáìnì tuntun, àti òróró sí i yín, a ó sì fi wọn tẹ́ yín lọ́rùn; Èmi kì yóò sì fi yín ṣe ẹ̀gàn mọ́ láàrín àwọn aláìkọlà.
Joel 2:19 in English
Joel 2:19 · Berean Standard Bible
And the LORD answered His people: “Behold, I will send you grain, new wine, and oil, and by them you will be satisfied. I will never again make you a reproach among the nations.
Context
17Jẹ́ kí àwọn àlùfáà, àwọn ìránṣẹ́ Olúwa,
sọkún láàrín ìloro àti pẹpẹ.
Sí jẹ́ kí wọn wí pé, “Dá àwọn ènìyàn rẹ sí, Olúwa.
Má sì ṣe fi ìní rẹ fun ẹ̀gàn,
tí yóò sì di òwe ní àárín àwọn kèfèrí.
Èéṣe tí wọn yóò fi wí láàrín àwọn ènìyàn pé,
‘Ọlọ́run wọn ha da?’ ” 18Nígbà náà ní Olúwa yóò jowú fún ilẹ̀ rẹ̀,
yóò sì káàánú fún ènìyàn rẹ̀. 19Nítòótọ́, Olúwa yóò dá wọn lóhùn, yóò sì wí fun àwọn ènìyàn rẹ̀ pé:
“Wò ó èmi yóò rán ọkà, àti ọtí wáìnì tuntun, àti òróró sí i yín,
a ó sì fi wọn tẹ́ yín lọ́rùn;
Èmi kì yóò sì fi yín ṣe ẹ̀gàn mọ́
láàrín àwọn aláìkọlà. 20“Ṣùgbọ́n èmi yóò lé ogun àríwá jìnnà réré kúrò lọ́dọ̀ yín,
èmi yóò sì lé e lọ sí ilẹ̀ tí ó ṣá, tí ó sì di ahoro,
pẹ̀lú ojú rẹ̀ sí Òkun ìlà-oòrùn,
àti ẹ̀yìn rẹ̀ sí ìwọ̀-oòrùn Òkun.
Òórùn rẹ̀ yóò sì gòkè,
òórùn búburú rẹ̀ yóò sì gòkè.”
Nítòótọ́ ó ti ṣe ohun ńlá. 21Má bẹ̀rù, ìwọ ilẹ̀;
jẹ́ kí inú rẹ̀ dùn kí o sì yọ̀,
nítorí Olúwa ti ṣe ohun ńlá.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.