Native Bible

Joel 2:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ kó àwọn ènìyàn jọ, ẹ ya ìjọ sí mímọ́; ẹ pe àwọn àgbàgbà jọ, ẹ kó àwọn ọmọdé jọ, àti àwọn tí ń mú ọmú, jẹ kí ọkọ ìyàwó kúrò nínú ìyẹ̀wù rẹ̀. Kí ìyàwó sì kúrò nínú iyàrá rẹ̀.

Joel 2:16 in English

Joel 2:16 · Berean Standard Bible

Gather the people, sanctify the congregation, assemble the aged, gather the children, even those nursing at the breast. Let the bridegroom leave his room, and the bride her chamber.

Context

14Ta ni ó mọ̀ bí òun yóò yípadà, kí o sì ronúpìwàdà, kí ó sì fi ìbùkún sílẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀— àní ọrẹ-jíjẹ àti ọrẹ mímu fún Olúwa Ọlọ́run yín? 15Ẹ fún ìpè ní Sioni, ẹ ya àwẹ̀ kan sí mímọ́, ẹ pe àjọ tí ó ni ìrònú. 16Ẹ kó àwọn ènìyàn jọ, ẹ ya ìjọ sí mímọ́; ẹ pe àwọn àgbàgbà jọ, ẹ kó àwọn ọmọdé jọ, àti àwọn tí ń mú ọmú, jẹ kí ọkọ ìyàwó kúrò nínú ìyẹ̀wù rẹ̀. Kí ìyàwó sì kúrò nínú iyàrá rẹ̀. 17Jẹ́ kí àwọn àlùfáà, àwọn ìránṣẹ́ Olúwa, sọkún láàrín ìloro àti pẹpẹ. Sí jẹ́ kí wọn wí pé, “Dá àwọn ènìyàn rẹ sí, Olúwa. Má sì ṣe fi ìní rẹ fun ẹ̀gàn, tí yóò sì di òwe ní àárín àwọn kèfèrí. Èéṣe tí wọn yóò fi wí láàrín àwọn ènìyàn pé, ‘Ọlọ́run wọn ha da?’ ” 18Nígbà náà ní Olúwa yóò jowú fún ilẹ̀ rẹ̀, yóò sì káàánú fún ènìyàn rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.