Joẹli 2:14
Joel 2:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ta ni ó mọ̀ bí òun yóò yípadà, kí o sì ronúpìwàdà, kí ó sì fi ìbùkún sílẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀— àní ọrẹ-jíjẹ àti ọrẹ mímu fún Olúwa Ọlọ́run yín?
Joel 2:14 in English
Joel 2:14 · Berean Standard Bible
Who knows? He may turn and relent and leave a blessing behind Him— grain and drink offerings for the LORD your God.
Context
12“Ǹjẹ́ nítorí náà nísinsin yìí,” ni Olúwa wí,
“Ẹ fi gbogbo ọkàn yín yípadà sí mi,
àti pẹ̀lú àwẹ̀, àti pẹ̀lú ẹkún, àti pẹ̀lú ọ̀fọ̀.” 13Ẹ sì fa ọkàn yín ya,
kì í sì í ṣe aṣọ yín,
ẹ sì yípadà sí Olúwa Ọlọ́run yín,
nítorí tí o pọ̀ ní oore-ọ̀fẹ́,
ó sì kún fun àánú, ó lọ́ra láti bínú,
ó sì ṣeun púpọ̀, ó sì ronúpìwàdà láti ṣe búburú. 14Ta ni ó mọ̀ bí òun yóò yípadà, kí o sì ronúpìwàdà,
kí ó sì fi ìbùkún sílẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀—
àní ọrẹ-jíjẹ àti ọrẹ mímu
fún Olúwa Ọlọ́run yín? 15Ẹ fún ìpè ní Sioni,
ẹ ya àwẹ̀ kan sí mímọ́,
ẹ pe àjọ tí ó ni ìrònú. 16Ẹ kó àwọn ènìyàn jọ,
ẹ ya ìjọ sí mímọ́;
ẹ pe àwọn àgbàgbà jọ,
ẹ kó àwọn ọmọdé jọ,
àti àwọn tí ń mú ọmú,
jẹ kí ọkọ ìyàwó kúrò nínú ìyẹ̀wù rẹ̀.
Kí ìyàwó sì kúrò nínú iyàrá rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.