Native Bible

Joel 2:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ fún ìpè ní Sioni, ẹ ya àwẹ̀ kan sí mímọ́, ẹ pe àjọ tí ó ni ìrònú.

Joel 2:15 in English

Joel 2:15 · Berean Standard Bible

Blow the ram’s horn in Zion, consecrate a fast, proclaim a sacred assembly.

Context

13Ẹ sì fa ọkàn yín ya, kì í sì í ṣe aṣọ yín, ẹ sì yípadà sí Olúwa Ọlọ́run yín, nítorí tí o pọ̀ ní oore-ọ̀fẹ́, ó sì kún fun àánú, ó lọ́ra láti bínú, ó sì ṣeun púpọ̀, ó sì ronúpìwàdà láti ṣe búburú. 14Ta ni ó mọ̀ bí òun yóò yípadà, kí o sì ronúpìwàdà, kí ó sì fi ìbùkún sílẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀— àní ọrẹ-jíjẹ àti ọrẹ mímu fún Olúwa Ọlọ́run yín? 15Ẹ fún ìpè ní Sioni, ẹ ya àwẹ̀ kan sí mímọ́, ẹ pe àjọ tí ó ni ìrònú. 16Ẹ kó àwọn ènìyàn jọ, ẹ ya ìjọ sí mímọ́; ẹ pe àwọn àgbàgbà jọ, ẹ kó àwọn ọmọdé jọ, àti àwọn tí ń mú ọmú, jẹ kí ọkọ ìyàwó kúrò nínú ìyẹ̀wù rẹ̀. Kí ìyàwó sì kúrò nínú iyàrá rẹ̀. 17Jẹ́ kí àwọn àlùfáà, àwọn ìránṣẹ́ Olúwa, sọkún láàrín ìloro àti pẹpẹ. Sí jẹ́ kí wọn wí pé, “Dá àwọn ènìyàn rẹ sí, Olúwa. Má sì ṣe fi ìní rẹ fun ẹ̀gàn, tí yóò sì di òwe ní àárín àwọn kèfèrí. Èéṣe tí wọn yóò fi wí láàrín àwọn ènìyàn pé, ‘Ọlọ́run wọn ha da?’ ”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.