Jobu 42:6
Job 42:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ǹjẹ́ nítorí náà èmi kórìíra ara mi, mo sì ronúpìwàdà nínú ekuru àti eérú.”
Job 42:6 in English
Job 42:6 · Berean Standard Bible
Therefore I retract my words, and I repent in dust and ashes.”
Context
4“Ìwọ wí pé, ‘Gbọ́ tèmi báyìí,
èmi ó sì sọ; èmi ó béèrè lọ́wọ́ rẹ,
ìwọ yóò sì dá mi lóhùn.’ 5Etí mi sì ti gbọ́ nípa rẹ,
ṣùgbọ́n nísinsin yìí ojú mi ti rí ọ. 6Ǹjẹ́ nítorí náà èmi kórìíra ara mi,
mo sì ronúpìwàdà nínú ekuru àti eérú.” 7Bẹ́ẹ̀ ó sì rí, lẹ́yìn ìgbà tí Olúwa ti sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún Jobu, Olúwa sì wí fún Elifasi, ará Temani pé, mo bínú sí ọ, àti sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ méjèèjì, nítorí pé ẹ̀yin kò sọ̀rọ̀, ní ti èmi, ohun tí ó tọ́, bí Jobu ìránṣẹ́ mi ti sọ. 8Nítorí náà, ẹ mú akọ ẹgbọrọ màlúù méje, àti àgbò méje, kí ẹ sì tọ̀ Jobu ìránṣẹ́ mi lọ, kí ẹ sì fi rú ẹbọ sísun fún ara yín; Jobu ìránṣẹ́ mi yóò sì gbàdúrà fún yin; nítorí pé àdúrà rẹ̀ ní èmi yóò gbà; kí èmi kí ó má ba ṣe si yín bí ìṣìnà yín, ní ti pé ẹ̀yin kò sọ̀rọ̀ ohun tí ó tọ́ sí mi bi Jobu ìránṣẹ́ mi ti ṣe.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.