Native Bible

Job 42:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bẹ́ẹ̀ ó sì rí, lẹ́yìn ìgbà tí Olúwa ti sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún Jobu, Olúwa sì wí fún Elifasi, ará Temani pé, mo bínú sí ọ, àti sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ méjèèjì, nítorí pé ẹ̀yin kò sọ̀rọ̀, ní ti èmi, ohun tí ó tọ́, bí Jobu ìránṣẹ́ mi ti sọ.

Job 42:7 in English

Job 42:7 · Berean Standard Bible

After the LORD had spoken these words to Job, He said to Eliphaz the Temanite, “My wrath is kindled against you and your two friends. For you have not spoken about Me accurately, as My servant Job has.

Context

5Etí mi sì ti gbọ́ nípa rẹ, ṣùgbọ́n nísinsin yìí ojú mi ti rí ọ. 6Ǹjẹ́ nítorí náà èmi kórìíra ara mi, mo sì ronúpìwàdà nínú ekuru àti eérú.” 7Bẹ́ẹ̀ ó sì rí, lẹ́yìn ìgbà tí Olúwa ti sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún Jobu, Olúwa sì wí fún Elifasi, ará Temani pé, mo bínú sí ọ, àti sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ méjèèjì, nítorí pé ẹ̀yin kò sọ̀rọ̀, ní ti èmi, ohun tí ó tọ́, bí Jobu ìránṣẹ́ mi ti sọ. 8Nítorí náà, ẹ mú akọ ẹgbọrọ màlúù méje, àti àgbò méje, kí ẹ sì tọ̀ Jobu ìránṣẹ́ mi lọ, kí ẹ sì fi rú ẹbọ sísun fún ara yín; Jobu ìránṣẹ́ mi yóò sì gbàdúrà fún yin; nítorí pé àdúrà rẹ̀ ní èmi yóò gbà; kí èmi kí ó má ba ṣe si yín bí ìṣìnà yín, ní ti pé ẹ̀yin kò sọ̀rọ̀ ohun tí ó tọ́ sí mi bi Jobu ìránṣẹ́ mi ti ṣe. 9Bẹ́ẹ̀ ní Elifasi, ara Temani, àti Bilidadi, ará Ṣuhi, àti Sofari, ará Naama lọ, wọ́n sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún wọn. Olúwa sì gbọ́ àdúrà Jobu.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.