Native Bible

Job 36:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí ìbínú ń bẹ, ṣọ́ra kí òtítọ́ rẹ máa bá a tàn ọ; láti jẹ́ kí títóbi rẹ mú ọ ṣìnà.

Job 36:18 in English

Job 36:18 · Berean Standard Bible

Be careful that no one lures you with riches; do not let a large bribe lead you astray.

Context

16“Bẹ́ẹ̀ ni pẹ̀lúpẹ̀lú ó fa wọn yọ láti inú ìhágágá sí ibi gbòòrò, sí ibi tí ó ní ààyè tí kò ní wàhálà nínú rẹ̀, ohun tí a sì gbé kalẹ̀ ní tábìlì rẹ̀ jẹ́ kìkì ọ̀rá oúnjẹ tí ó fẹ́. 17Ṣùgbọ́n ìwọ kún fún ìdájọ́ àwọn búburú; ìdájọ́ àti òtítọ́ dì ọ́ mú. 18Nítorí ìbínú ń bẹ, ṣọ́ra kí òtítọ́ rẹ máa bá a tàn ọ; láti jẹ́ kí títóbi rẹ mú ọ ṣìnà. 19Ọrọ̀ rẹ pọ̀ tó, tí wàhálà kì yóò fi dé bá ọ bí? Tàbí ipa agbára rẹ? 20Má ṣe ìfẹ́ òru, nígbà tí a ń ké àwọn orílẹ̀-èdè kúrò ní ipò wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.