Jobu 36:17
Job 36:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n ìwọ kún fún ìdájọ́ àwọn búburú; ìdájọ́ àti òtítọ́ dì ọ́ mú.
Job 36:17 in English
Job 36:17 · Berean Standard Bible
But now you are laden with the judgment due the wicked; judgment and justice have seized you.
Context
15Òun gba òtòṣì nínú ìpọ́njú wọn,
a sì sọ̀rọ̀ sí wọn ní etí nínú ìnira wọn. 16“Bẹ́ẹ̀ ni pẹ̀lúpẹ̀lú ó fa wọn yọ láti inú ìhágágá sí ibi gbòòrò,
sí ibi tí ó ní ààyè tí kò ní wàhálà nínú rẹ̀,
ohun tí a sì gbé kalẹ̀ ní tábìlì rẹ̀ jẹ́ kìkì ọ̀rá oúnjẹ tí ó fẹ́. 17Ṣùgbọ́n ìwọ kún fún ìdájọ́ àwọn búburú;
ìdájọ́ àti òtítọ́ dì ọ́ mú. 18Nítorí ìbínú ń bẹ, ṣọ́ra kí òtítọ́ rẹ máa bá a tàn ọ;
láti jẹ́ kí títóbi rẹ mú ọ ṣìnà. 19Ọrọ̀ rẹ pọ̀ tó, tí wàhálà kì yóò fi dé bá ọ bí?
Tàbí ipa agbára rẹ?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.