Jobu 36:15
Job 36:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Òun gba òtòṣì nínú ìpọ́njú wọn, a sì sọ̀rọ̀ sí wọn ní etí nínú ìnira wọn.
Job 36:15 in English
Job 36:15 · Berean Standard Bible
God rescues the afflicted by their affliction * and opens their ears in oppression.
Context
13“Ṣùgbọ́n àwọn àgàbàgebè ní ayé kó ìbínú jọ;
wọn kò kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nígbà tí ó bá wọ́n wí. 14Nígbà náà ni ọkàn wọn yóò kú ní èwe,
ní àárín àwọn ọkùnrin alágbèrè ojúbọ òrìṣà. 15Òun gba òtòṣì nínú ìpọ́njú wọn,
a sì sọ̀rọ̀ sí wọn ní etí nínú ìnira wọn. 16“Bẹ́ẹ̀ ni pẹ̀lúpẹ̀lú ó fa wọn yọ láti inú ìhágágá sí ibi gbòòrò,
sí ibi tí ó ní ààyè tí kò ní wàhálà nínú rẹ̀,
ohun tí a sì gbé kalẹ̀ ní tábìlì rẹ̀ jẹ́ kìkì ọ̀rá oúnjẹ tí ó fẹ́. 17Ṣùgbọ́n ìwọ kún fún ìdájọ́ àwọn búburú;
ìdájọ́ àti òtítọ́ dì ọ́ mú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.