Native Bible

Job 34:35 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

‘Jobu ti fi àìmọ̀ sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì ṣe aláìgbọ́n.’

Job 34:35 in English

Job 34:35 · Berean Standard Bible

‘Job speaks without knowledge; his words lack insight.’

Context

33Ǹjẹ́ bí ti inú rẹ̀ ni ki òun ó san ẹ̀ṣẹ̀ padà? Ǹjẹ́ òun yóò san án padà bí ìwọ bá kọ̀ ọ́ láti jẹ́wọ́, ìwọ gbọdọ̀ yan, kì í ṣe èmi. Nítorí náà sọ ohun tí o mọ̀, pẹ̀lúpẹ̀lú ohun tí ìwọ mọ̀, sọ ọ́! 34“Àwọn ènìyàn amòye yóò wí fún mi, àti pẹ̀lúpẹ̀lú ẹnikẹ́ni tí í ṣe ọlọ́gbọ́n tí ó sì gbọ́ mi pé, 35‘Jobu ti fi àìmọ̀ sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì ṣe aláìgbọ́n.’ 36Ìfẹ́ mi ni kí a dán Jobu wò dé òpin, nítorí ìdáhùn rẹ̀ dàbí i ti ènìyàn búburú. 37Nítorí pe ó fi ìṣọ̀tẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀; ó pàtẹ́wọ́ ní àárín wa, ó sì sọ ọ̀rọ̀ odi púpọ̀ sí Ọlọ́run.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.