Native Bible

Job 31:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

kí ni èmi ó ha ṣe nígbà tí Ọlọ́run bá dìde? Nígbà tí ó bá sì ṣe ìbẹ̀wò, ohùn kí ni èmi ó dá?

Job 31:14 in English

Job 31:14 · Berean Standard Bible

what will I do when God rises to judge? How will I answer when called to account?

Context

12Nítorí pé iná ní èyí tí ó jó dé ibi ìparun, tí ìbá sì fa gbòǹgbò ohun ìbísí mi gbogbo tu. 13“Tí mo bá sì ṣe àìka ọ̀ràn ìránṣẹ́kùnrin mi tàbí ìránṣẹ́bìnrin mi sí, nígbà tí wọ́n bá ń bá mi jà; 14kí ni èmi ó ha ṣe nígbà tí Ọlọ́run bá dìde? Nígbà tí ó bá sì ṣe ìbẹ̀wò, ohùn kí ni èmi ó dá? 15Ẹni tí ó dá mi ní inú kọ́ ni ó dá a? Ẹnìkan náà kí ó mọ wá ní inú ìyá wa? 16“Bí mo bá fa ọwọ́ sẹ́yìn fún ìfẹ́ inú tálákà, tàbí bí mo bá sì mú kí ojú opó rẹ̀wẹ̀sì,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.