Jobu 31:15
Job 31:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹni tí ó dá mi ní inú kọ́ ni ó dá a? Ẹnìkan náà kí ó mọ wá ní inú ìyá wa?
Job 31:15 in English
Job 31:15 · Berean Standard Bible
Did not He who made me in the womb also make them? Did not the same One form us in the womb?
Context
13“Tí mo bá sì ṣe àìka ọ̀ràn ìránṣẹ́kùnrin mi
tàbí ìránṣẹ́bìnrin mi sí,
nígbà tí wọ́n bá ń bá mi jà; 14kí ni èmi ó ha ṣe nígbà tí Ọlọ́run bá dìde?
Nígbà tí ó bá sì ṣe ìbẹ̀wò, ohùn kí ni èmi ó dá? 15Ẹni tí ó dá mi ní inú kọ́ ni ó dá a?
Ẹnìkan náà kí ó mọ wá ní inú ìyá wa? 16“Bí mo bá fa ọwọ́ sẹ́yìn fún ìfẹ́ inú tálákà,
tàbí bí mo bá sì mú kí ojú opó rẹ̀wẹ̀sì, 17tàbí tí mo bá nìkan bu òkèlè mi jẹ,
tí aláìní baba kò jẹ nínú rẹ̀;
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.