Native Bible

Job 24:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ojú alágbèrè pẹ̀lú dúró kí ilẹ̀ ṣú díẹ̀; ‘Ó ní, ojú ẹnìkan kì yóò rí mi,’ ó sì fi ìbòjú bojú rẹ̀.

Job 24:15 in English

Job 24:15 · Berean Standard Bible

The eye of the adulterer watches for twilight. Thinking, ‘No eye will see me,’ he covers his face.

Context

13“Àwọn ni ó wà nínú àwọn tí ó ṣọ̀tẹ̀ sí ìmọ́lẹ̀, wọn kò mọ̀ ipa ọ̀nà rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò dúró nípa ọ̀nà rẹ̀. 14Apànìyàn a dìde ní àfẹ̀mọ́júmọ́, a sì pa tálákà àti aláìní, àti ní òru a di olè. 15Ojú alágbèrè pẹ̀lú dúró kí ilẹ̀ ṣú díẹ̀; ‘Ó ní, ojú ẹnìkan kì yóò rí mi,’ ó sì fi ìbòjú bojú rẹ̀. 16Ní òkùnkùn wọn á rúnlẹ̀ wọlé, tí wọ́n ti fi ojú sọ fún ara wọn ní ọ̀sán, wọn kò mọ̀ ìmọ́lẹ̀. 17Nítorí pé bí òru dúdú ní òwúrọ̀ fún gbogbo wọn; nítorí tí wọn sì mọ̀ ìbẹ̀rù òkùnkùn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.