Native Bible

Job 24:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Apànìyàn a dìde ní àfẹ̀mọ́júmọ́, a sì pa tálákà àti aláìní, àti ní òru a di olè.

Job 24:14 in English

Job 24:14 · Berean Standard Bible

When daylight is gone, the murderer rises to kill the poor and needy; in the night he is like a thief.

Context

12Àwọn ènìyàn ń kérora láti ìlú wá, ọkàn àwọn ẹni tí ó gbọgbẹ́ kígbe sókè fún ìrànlọ́wọ́ síbẹ̀ Ọlọ́run kò kíyèsi àṣìṣe náà. 13“Àwọn ni ó wà nínú àwọn tí ó ṣọ̀tẹ̀ sí ìmọ́lẹ̀, wọn kò mọ̀ ipa ọ̀nà rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò dúró nípa ọ̀nà rẹ̀. 14Apànìyàn a dìde ní àfẹ̀mọ́júmọ́, a sì pa tálákà àti aláìní, àti ní òru a di olè. 15Ojú alágbèrè pẹ̀lú dúró kí ilẹ̀ ṣú díẹ̀; ‘Ó ní, ojú ẹnìkan kì yóò rí mi,’ ó sì fi ìbòjú bojú rẹ̀. 16Ní òkùnkùn wọn á rúnlẹ̀ wọlé, tí wọ́n ti fi ojú sọ fún ara wọn ní ọ̀sán, wọn kò mọ̀ ìmọ́lẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.