Jobu 24:13
Job 24:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Àwọn ni ó wà nínú àwọn tí ó ṣọ̀tẹ̀ sí ìmọ́lẹ̀, wọn kò mọ̀ ipa ọ̀nà rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò dúró nípa ọ̀nà rẹ̀.
Job 24:13 in English
Job 24:13 · Berean Standard Bible
Then there are those who rebel against the light, not knowing its ways or staying on its paths.
Context
11Àwọn ẹni tí ń fún òróró nínú àgbàlá wọn,
tí wọ́n sì ń tẹ ìfúntí àjàrà, síbẹ̀ òǹgbẹ sì ń gbẹ wọn. 12Àwọn ènìyàn ń kérora láti ìlú wá,
ọkàn àwọn ẹni tí ó gbọgbẹ́ kígbe sókè fún ìrànlọ́wọ́
síbẹ̀ Ọlọ́run kò kíyèsi àṣìṣe náà. 13“Àwọn ni ó wà nínú àwọn tí ó ṣọ̀tẹ̀ sí ìmọ́lẹ̀,
wọn kò mọ̀ ipa ọ̀nà rẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni wọn kò dúró nípa ọ̀nà rẹ̀. 14Apànìyàn a dìde ní àfẹ̀mọ́júmọ́,
a sì pa tálákà àti aláìní,
àti ní òru a di olè. 15Ojú alágbèrè pẹ̀lú dúró kí ilẹ̀ ṣú díẹ̀;
‘Ó ní, ojú ẹnìkan kì yóò rí mi,’
ó sì fi ìbòjú bojú rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.