Jobu 23:15
Job 23:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí náà ni ara kò ṣe rọ̀ mí níwájú rẹ̀; nígbà tí mo bá rò ó, ẹ̀rù a bà mi.
Job 23:15 in English
Job 23:15 · Berean Standard Bible
Therefore I am terrified in His presence; when I consider this, I fear Him.
Context
13“Ṣùgbọ́n onínú kan ni òun, ta ni yóò sì yí i padà?
Èyí tí ọkàn rẹ̀ sì ti fẹ́, èyí náà ní í ṣe. 14Nítòótọ́ ohun tí a ti yàn fún mi ní í ṣe;
ọ̀pọ̀lọpọ̀ irú ohun bẹ́ẹ̀ ni ó wà ní ọwọ́ rẹ̀. 15Nítorí náà ni ara kò ṣe rọ̀ mí níwájú rẹ̀;
nígbà tí mo bá rò ó, ẹ̀rù a bà mi. 16Nítorí pé Ọlọ́run ti pá mi ní àyà,
Olódùmarè sì ń dààmú mi. 17Nítorí tí a kò tí ì ké mi kúrò níwájú òkùnkùn,
bẹ́ẹ̀ ni kò pa òkùnkùn biribiri mọ́ kúrò níwájú mi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.