Jobu 21:11
Job 21:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọn a máa rán àwọn ọmọ wọn wẹ́wẹ́ jáde bí agbo ẹran, àwọn ọmọ wọn a sì máa jo kiri.
Job 21:11 in English
Job 21:11 · Berean Standard Bible
They send forth their little ones like a flock; their children skip about,
Context
9Ilé wọn wà láìní ewu àti ẹ̀rù,
bẹ́ẹ̀ ni ọ̀pá ìbínú Ọlọ́run kò sí lára wọn. 10Akọ màlúù wọn a máa gùn, kì í sì tàsé;
abo màlúù wọn a máa bí, kì í sì í ṣẹ́yun. 11Wọn a máa rán àwọn ọmọ wọn
wẹ́wẹ́ jáde bí agbo ẹran, àwọn ọmọ wọn a sì máa jo kiri. 12Wọ́n mú ohun ọ̀nà orin, ìlù àti haapu;
wọ́n sì ń yọ̀ sí ohùn fèrè. 13Wọ́n n lo ọjọ́ wọn nínú ọrọ̀;
wọn sì lọ sí ipò òkú ní àlàáfíà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.