Jobu 21:12
Job 21:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ́n mú ohun ọ̀nà orin, ìlù àti haapu; wọ́n sì ń yọ̀ sí ohùn fèrè.
Job 21:12 in English
Job 21:12 · Berean Standard Bible
singing to the tambourine and lyre and making merry at the sound of the flute.
Context
10Akọ màlúù wọn a máa gùn, kì í sì tàsé;
abo màlúù wọn a máa bí, kì í sì í ṣẹ́yun. 11Wọn a máa rán àwọn ọmọ wọn
wẹ́wẹ́ jáde bí agbo ẹran, àwọn ọmọ wọn a sì máa jo kiri. 12Wọ́n mú ohun ọ̀nà orin, ìlù àti haapu;
wọ́n sì ń yọ̀ sí ohùn fèrè. 13Wọ́n n lo ọjọ́ wọn nínú ọrọ̀;
wọn sì lọ sí ipò òkú ní àlàáfíà. 14Nítorí náà ni wọ́n ṣe wí fún Ọlọ́run pé, ‘Lọ kúrò lọ́dọ̀ wa!’
Nítorí pé wọn kò fẹ́ ìmọ̀ ipa ọ̀nà rẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.