Native Bible

John 9:31 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwa mọ̀ pé Ọlọ́run kì í gbọ́ ti ẹlẹ́ṣẹ̀; ṣùgbọ́n bí ẹnìkan bá ṣe olùfọkànsìn sí Ọlọ́run, tí ó bá sì ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀, Òun ni ó ń gbọ́ tirẹ̀.

John 9:31 in English

John 9:31 · Berean Standard Bible

We know that God does not listen to sinners, but He does listen to the one who worships Him and does His will.

Context

29Àwa mọ̀ pé Ọlọ́run bá Mose sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti eléyìí, àwa kò mọ ibi tí ó ti wá.” 30Ọkùnrin náà dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ohun ìyanu sá à ni èyí, pé ẹ̀yin kò mọ ibi tí ó tí wá, ṣùgbọ́n òun sá à ti là mí lójú. 31Àwa mọ̀ pé Ọlọ́run kì í gbọ́ ti ẹlẹ́ṣẹ̀; ṣùgbọ́n bí ẹnìkan bá ṣe olùfọkànsìn sí Ọlọ́run, tí ó bá sì ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀, Òun ni ó ń gbọ́ tirẹ̀. 32Láti ìgbà tí ayé ti ṣẹ̀, a kò ì tí ì gbọ́ pé ẹnìkan la ojú ẹni tí a bí ní afọ́jú rí. 33Ìbá ṣe pé ọkùnrin yìí kò ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, kì bá tí lè ṣe ohunkóhun.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.