Native Bible

John 9:32 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Láti ìgbà tí ayé ti ṣẹ̀, a kò ì tí ì gbọ́ pé ẹnìkan la ojú ẹni tí a bí ní afọ́jú rí.

John 9:32 in English

John 9:32 · Berean Standard Bible

Never before has anyone heard of opening the eyes of a man born blind.

Context

30Ọkùnrin náà dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ohun ìyanu sá à ni èyí, pé ẹ̀yin kò mọ ibi tí ó tí wá, ṣùgbọ́n òun sá à ti là mí lójú. 31Àwa mọ̀ pé Ọlọ́run kì í gbọ́ ti ẹlẹ́ṣẹ̀; ṣùgbọ́n bí ẹnìkan bá ṣe olùfọkànsìn sí Ọlọ́run, tí ó bá sì ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀, Òun ni ó ń gbọ́ tirẹ̀. 32Láti ìgbà tí ayé ti ṣẹ̀, a kò ì tí ì gbọ́ pé ẹnìkan la ojú ẹni tí a bí ní afọ́jú rí. 33Ìbá ṣe pé ọkùnrin yìí kò ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, kì bá tí lè ṣe ohunkóhun.” 34Sí èyí, wọ́n fèsì pé, “Láti ìbí ni o tì jíngírí nínú ẹ̀ṣẹ̀, ìwọ ha fẹ́ kọ́ wa bí?” Wọ́n sì tì í sóde.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.