Native Bible

John 9:30 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọkùnrin náà dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ohun ìyanu sá à ni èyí, pé ẹ̀yin kò mọ ibi tí ó tí wá, ṣùgbọ́n òun sá à ti là mí lójú.

John 9:30 in English

John 9:30 · Berean Standard Bible

“That is remarkable indeed!” the man said. “You do not know where He is from, and yet He opened my eyes.

Context

28Wọ́n sì fi í ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n sì wí pé, “Ìwọ ni ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ṣùgbọ́n ọmọ-ẹ̀yìn Mose ni àwa. 29Àwa mọ̀ pé Ọlọ́run bá Mose sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti eléyìí, àwa kò mọ ibi tí ó ti wá.” 30Ọkùnrin náà dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ohun ìyanu sá à ni èyí, pé ẹ̀yin kò mọ ibi tí ó tí wá, ṣùgbọ́n òun sá à ti là mí lójú. 31Àwa mọ̀ pé Ọlọ́run kì í gbọ́ ti ẹlẹ́ṣẹ̀; ṣùgbọ́n bí ẹnìkan bá ṣe olùfọkànsìn sí Ọlọ́run, tí ó bá sì ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀, Òun ni ó ń gbọ́ tirẹ̀. 32Láti ìgbà tí ayé ti ṣẹ̀, a kò ì tí ì gbọ́ pé ẹnìkan la ojú ẹni tí a bí ní afọ́jú rí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.