Johanu 9:29
John 9:29 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwa mọ̀ pé Ọlọ́run bá Mose sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti eléyìí, àwa kò mọ ibi tí ó ti wá.”
John 9:29 in English
John 9:29 · Berean Standard Bible
We know that God spoke to Moses, but we do not know where this man is from.”
Context
27Ó dá wọn lóhùn wí pé, “Èmi ti sọ fún yín tẹ́lẹ̀, ẹ̀yin kò sì gbọ́, nítorí kín ni ẹ̀yin ṣe ń fẹ́ tún gbọ́? Ẹ̀yin pẹ̀lú ń fẹ́ ṣe ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bí?” 28Wọ́n sì fi í ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n sì wí pé, “Ìwọ ni ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ṣùgbọ́n ọmọ-ẹ̀yìn Mose ni àwa. 29Àwa mọ̀ pé Ọlọ́run bá Mose sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti eléyìí, àwa kò mọ ibi tí ó ti wá.” 30Ọkùnrin náà dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ohun ìyanu sá à ni èyí, pé ẹ̀yin kò mọ ibi tí ó tí wá, ṣùgbọ́n òun sá à ti là mí lójú. 31Àwa mọ̀ pé Ọlọ́run kì í gbọ́ ti ẹlẹ́ṣẹ̀; ṣùgbọ́n bí ẹnìkan bá ṣe olùfọkànsìn sí Ọlọ́run, tí ó bá sì ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀, Òun ni ó ń gbọ́ tirẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.