Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Sọ pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “ ‘Òkú àwọn ènìyàn yóò ṣubú bí ààtàn ní oko gbangba àti bí ìbùkúnwọ́ lẹ́yìn olùkórè láìsí ẹnìkankan láti kó wọn jọ.’ ”

Jeremiah 9:22 in English

Jeremiah 9:22 · Berean Standard Bible

Declare that this is what the LORD says: “The corpses of men will fall like dung upon the open field, like newly cut grain behind the reaper, with no one to gather it.”

Context

20Nísinsin yìí, ẹ̀yin obìnrin ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa; ṣí etí yín sí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ. Kọ́ àwọn ọmọbìnrin yín ní ìpohùnréré ẹkún, kí ẹ sì kọ́ ara yín ní arò. 21Ikú ti gba ojú fèrèsé wa wọlé ó sì ti wọ odi alágbára wa ó ti ké àwọn ọmọ kúrò ní àdúgbò àti àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin kúrò ní gbọ̀ngàn ìta gbangba. 22Sọ pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “ ‘Òkú àwọn ènìyàn yóò ṣubú bí ààtàn ní oko gbangba àti bí ìbùkúnwọ́ lẹ́yìn olùkórè láìsí ẹnìkankan láti kó wọn jọ.’ ” 23Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Má ṣe jẹ́ kí ọlọ́gbọ́n yangàn nítorí agbára ọgbọ́n rẹ̀, tàbí alágbára nítorí agbára rẹ̀, tàbí ọlọ́rọ̀ nítorí ọrọ̀ rẹ̀. 24Ẹ jẹ́ kí ẹni tí ń ṣògo nípa èyí nì wí pé: òun ní òye, òun sì mọ̀ mí wí pé, Èmi ni Olúwa tí ń ṣe òtítọ́, ìdájọ́ àti òdodo ní ayé, nínú èyí ni mo ní inú dídùn sí,” Olúwa wí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.