Jeremiah 9:23
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Má ṣe jẹ́ kí ọlọ́gbọ́n yangàn nítorí agbára ọgbọ́n rẹ̀, tàbí alágbára nítorí agbára rẹ̀, tàbí ọlọ́rọ̀ nítorí ọrọ̀ rẹ̀.
Jeremiah 9:23 in English
Jeremiah 9:23 · Berean Standard Bible
This is what the LORD says: “Let not the wise man boast in his wisdom, nor the strong man in his strength, nor the wealthy man in his riches.
Context
21Ikú ti gba ojú fèrèsé wa wọlé
ó sì ti wọ odi alágbára wa
ó ti ké àwọn ọmọ kúrò ní àdúgbò
àti àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin kúrò ní gbọ̀ngàn ìta gbangba. 22Sọ pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí:
“ ‘Òkú àwọn ènìyàn yóò ṣubú
bí ààtàn ní oko gbangba
àti bí ìbùkúnwọ́ lẹ́yìn olùkórè
láìsí ẹnìkankan láti kó wọn jọ.’ ” 23Èyí ni ohun tí Olúwa wí:
“Má ṣe jẹ́ kí ọlọ́gbọ́n yangàn nítorí agbára ọgbọ́n rẹ̀,
tàbí alágbára nítorí agbára rẹ̀,
tàbí ọlọ́rọ̀ nítorí ọrọ̀ rẹ̀. 24Ẹ jẹ́ kí ẹni tí ń ṣògo nípa èyí nì wí pé:
òun ní òye, òun sì mọ̀ mí wí pé,
Èmi ni Olúwa tí ń ṣe òtítọ́,
ìdájọ́ àti òdodo ní ayé,
nínú èyí ni mo ní inú dídùn sí,”
Olúwa wí. 25“Ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí, “tí Èmi yóò fi ìyà jẹ gbogbo àwọn tí a kọ ilà fún nínú ara nìkan.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.