Jeremiah 9:24
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ jẹ́ kí ẹni tí ń ṣògo nípa èyí nì wí pé: òun ní òye, òun sì mọ̀ mí wí pé, Èmi ni Olúwa tí ń ṣe òtítọ́, ìdájọ́ àti òdodo ní ayé, nínú èyí ni mo ní inú dídùn sí,” Olúwa wí.
Jeremiah 9:24 in English
Jeremiah 9:24 · Berean Standard Bible
But let him who boasts boast in this, that he understands and knows Me, that I am the LORD,* who exercises loving devotion,* justice and righteousness on the earth— for I delight in these things,” declares the LORD.
Context
22Sọ pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí:
“ ‘Òkú àwọn ènìyàn yóò ṣubú
bí ààtàn ní oko gbangba
àti bí ìbùkúnwọ́ lẹ́yìn olùkórè
láìsí ẹnìkankan láti kó wọn jọ.’ ” 23Èyí ni ohun tí Olúwa wí:
“Má ṣe jẹ́ kí ọlọ́gbọ́n yangàn nítorí agbára ọgbọ́n rẹ̀,
tàbí alágbára nítorí agbára rẹ̀,
tàbí ọlọ́rọ̀ nítorí ọrọ̀ rẹ̀. 24Ẹ jẹ́ kí ẹni tí ń ṣògo nípa èyí nì wí pé:
òun ní òye, òun sì mọ̀ mí wí pé,
Èmi ni Olúwa tí ń ṣe òtítọ́,
ìdájọ́ àti òdodo ní ayé,
nínú èyí ni mo ní inú dídùn sí,”
Olúwa wí. 25“Ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí, “tí Èmi yóò fi ìyà jẹ gbogbo àwọn tí a kọ ilà fún nínú ara nìkan. 26Ejibiti, Juda, Edomu, Ammoni, Moabu àti gbogbo àwọn tí ń gbé ní ọ̀nà jíjìn réré ní aginjù. Nítorí pé gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí jẹ́ aláìkọlà gbogbo àwọn ará ilé Israẹli sì jẹ́ aláìkọlà ọkàn.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.