Jeremiah 8:13
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“ ‘Èmi yóò mú ìkórè wọn kúrò, ni Olúwa wí. Kì yóò sí èso lórí igi àjàrà. Kì yóò sí ọ̀pọ̀tọ́ lórí igi, ewé wọn yóò sì rẹ̀ sílẹ̀. Ohun tí mo ti fi fún wọn ni à ó gbà kúrò.’ ”
Jeremiah 8:13 in English
Jeremiah 8:13 · Berean Standard Bible
I will take away their harvest, declares the LORD. There will be no grapes on the vine, nor figs on the tree, and even the leaf will wither. Whatever I have given them will be lost to them.”
Context
11Wọ́n tọ́jú ọgbẹ́ àwọn ènìyàn mi
gẹ́gẹ́ bí èyí tí kò jinlẹ̀.
“Àlàáfíà, àlàáfíà,” ni wọ́n ń wí,
nígbà tí kò sí àlàáfíà. 12Ǹjẹ́ wọ́n tijú fún ìṣe ìríra wọn?
Bẹ́ẹ̀ kọ́, wọn kò ní ìtìjú rárá;
wọn kò tilẹ̀ mọ bí wọ́n ti ṣe ń tì jú.
Nítorí náà wọn yóò ṣubú pẹ̀lú àwọn tó ti ṣubú,
a ó sì wó wọ́n lulẹ̀ nígbà tí a bá bẹ̀ wọ́n wò,
ni Olúwa wí. 13“ ‘Èmi yóò mú ìkórè wọn kúrò,
ni Olúwa wí.
Kì yóò sí èso lórí igi àjàrà.
Kì yóò sí ọ̀pọ̀tọ́ lórí igi,
ewé wọn yóò sì rẹ̀ sílẹ̀.
Ohun tí mo ti fi fún wọn
ni à ó gbà kúrò.’ ” 14“Èéṣe tí àwa fi jókòó ní ibí yìí?
A kó ara wa jọ!
Jẹ́ kí a sálọ sí ìlú olódi
kí a sì ṣègbé síbẹ̀.
Nítorí tí Olúwa Ọlọ́run wa ti pinnu pé a ó ṣègbé.
Yóò sì fún wa ní omi onímájèlé mu,
nítorí àwa ti ṣẹ̀ sí i. 15Àwa ń retí àlàáfíà
kò sí ìre kan,
tí ó wá ní ìgbà ìmúláradá
bí kò ṣe ìpayà nìkan.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.