Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ǹjẹ́ wọ́n tijú fún ìṣe ìríra wọn? Bẹ́ẹ̀ kọ́, wọn kò ní ìtìjú rárá; wọn kò tilẹ̀ mọ bí wọ́n ti ṣe ń tì jú. Nítorí náà wọn yóò ṣubú pẹ̀lú àwọn tó ti ṣubú, a ó sì wó wọ́n lulẹ̀ nígbà tí a bá bẹ̀ wọ́n wò, ni Olúwa wí.

Jeremiah 8:12 in English

Jeremiah 8:12 · Berean Standard Bible

Are they ashamed of the abomination they have committed? No, they have no shame at all; they do not even know how to blush. So they will fall among the fallen; when I punish them, they will collapse, says the LORD.

Context

10Nítorí náà, èmi yóò fi ìyàwó wọn fún àwọn ọkùnrin mìíràn àti ilẹ̀ wọn fún àwọn ẹlòmíràn. Láti èyí tó kéré jù dé èyí tó dàgbà jù, gbogbo wọn ni èrè àjẹjù ń jẹ lógún; àwọn wòlíì àti àwọn àlùfáà pẹ̀lú ń hùwà ẹ̀tàn. 11Wọ́n tọ́jú ọgbẹ́ àwọn ènìyàn mi gẹ́gẹ́ bí èyí tí kò jinlẹ̀. “Àlàáfíà, àlàáfíà,” ni wọ́n ń wí, nígbà tí kò sí àlàáfíà. 12Ǹjẹ́ wọ́n tijú fún ìṣe ìríra wọn? Bẹ́ẹ̀ kọ́, wọn kò ní ìtìjú rárá; wọn kò tilẹ̀ mọ bí wọ́n ti ṣe ń tì jú. Nítorí náà wọn yóò ṣubú pẹ̀lú àwọn tó ti ṣubú, a ó sì wó wọ́n lulẹ̀ nígbà tí a bá bẹ̀ wọ́n wò, ni Olúwa wí. 13“ ‘Èmi yóò mú ìkórè wọn kúrò, ni Olúwa wí. Kì yóò sí èso lórí igi àjàrà. Kì yóò sí ọ̀pọ̀tọ́ lórí igi, ewé wọn yóò sì rẹ̀ sílẹ̀. Ohun tí mo ti fi fún wọn ni à ó gbà kúrò.’ ” 14“Èéṣe tí àwa fi jókòó ní ibí yìí? A kó ara wa jọ! Jẹ́ kí a sálọ sí ìlú olódi kí a sì ṣègbé síbẹ̀. Nítorí tí Olúwa Ọlọ́run wa ti pinnu pé a ó ṣègbé. Yóò sì fún wa ní omi onímájèlé mu, nítorí àwa ti ṣẹ̀ sí i.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.