Jeremiah 8:10
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí náà, èmi yóò fi ìyàwó wọn fún àwọn ọkùnrin mìíràn àti ilẹ̀ wọn fún àwọn ẹlòmíràn. Láti èyí tó kéré jù dé èyí tó dàgbà jù, gbogbo wọn ni èrè àjẹjù ń jẹ lógún; àwọn wòlíì àti àwọn àlùfáà pẹ̀lú ń hùwà ẹ̀tàn.
Jeremiah 8:10 in English
Jeremiah 8:10 · Berean Standard Bible
Therefore I will give their wives to other men and their fields to new owners. For from the least of them to the greatest, all are greedy for gain; from prophet to priest, all practice deceit.
Context
8“ ‘Báwo ni ẹ̀yin ṣe lè wí pé, “Àwa gbọ́n,
nítorí a ní òfin Olúwa,”
nígbà tí ó jẹ́ pé kálámù èké àwọn akọ̀wé
ti àwọn sọ ọ́ di ẹ̀tàn. 9Ojú yóò ti àwọn ọlọ́gbọ́n,
a ó dà wọ́n láàmú, wọn yóò sì kó sí ìgbèkùn.
Nítorí wọ́n ti kọ ọ̀rọ̀ Olúwa,
irú ọgbọ́n wo ló kù tí wọ́n ní? 10Nítorí náà, èmi yóò fi ìyàwó wọn fún àwọn ọkùnrin mìíràn
àti ilẹ̀ wọn fún àwọn ẹlòmíràn.
Láti èyí tó kéré jù dé èyí tó dàgbà jù,
gbogbo wọn ni èrè àjẹjù ń jẹ lógún;
àwọn wòlíì àti àwọn àlùfáà
pẹ̀lú ń hùwà ẹ̀tàn. 11Wọ́n tọ́jú ọgbẹ́ àwọn ènìyàn mi
gẹ́gẹ́ bí èyí tí kò jinlẹ̀.
“Àlàáfíà, àlàáfíà,” ni wọ́n ń wí,
nígbà tí kò sí àlàáfíà. 12Ǹjẹ́ wọ́n tijú fún ìṣe ìríra wọn?
Bẹ́ẹ̀ kọ́, wọn kò ní ìtìjú rárá;
wọn kò tilẹ̀ mọ bí wọ́n ti ṣe ń tì jú.
Nítorí náà wọn yóò ṣubú pẹ̀lú àwọn tó ti ṣubú,
a ó sì wó wọ́n lulẹ̀ nígbà tí a bá bẹ̀ wọ́n wò,
ni Olúwa wí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.