Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwa ń retí àlàáfíà kò sí ìre kan, tí ó wá ní ìgbà ìmúláradá bí kò ṣe ìpayà nìkan.

Jeremiah 8:15 in English

Jeremiah 8:15 · Berean Standard Bible

We hoped for peace, but no good has come, for a time of healing, but there was only terror.

Context

13“ ‘Èmi yóò mú ìkórè wọn kúrò, ni Olúwa wí. Kì yóò sí èso lórí igi àjàrà. Kì yóò sí ọ̀pọ̀tọ́ lórí igi, ewé wọn yóò sì rẹ̀ sílẹ̀. Ohun tí mo ti fi fún wọn ni à ó gbà kúrò.’ ” 14“Èéṣe tí àwa fi jókòó ní ibí yìí? A kó ara wa jọ! Jẹ́ kí a sálọ sí ìlú olódi kí a sì ṣègbé síbẹ̀. Nítorí tí Olúwa Ọlọ́run wa ti pinnu pé a ó ṣègbé. Yóò sì fún wa ní omi onímájèlé mu, nítorí àwa ti ṣẹ̀ sí i. 15Àwa ń retí àlàáfíà kò sí ìre kan, tí ó wá ní ìgbà ìmúláradá bí kò ṣe ìpayà nìkan. 16Ìró ìfọn imú ẹṣin àwọn ọlọ̀tẹ̀ là ń gbọ́ láti Dani, yíyan àwọn akọ ẹṣin mú gbogbo ilẹ̀ wárìrì. Wọ́n wá láti pa ilẹ̀ náà run, gbogbo ohun tó wà níbẹ̀, ìlú náà àti gbogbo olùgbé ibẹ̀. 17“Wò ó, èmi yóò rán àwọn ejò olóró sí àárín yín, paramọ́lẹ̀ tí ẹ kò lè pa oró wọn, yóò sì bù yín jẹ,” ni Olúwa wí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.