Jeremiah 8:17
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Wò ó, èmi yóò rán àwọn ejò olóró sí àárín yín, paramọ́lẹ̀ tí ẹ kò lè pa oró wọn, yóò sì bù yín jẹ,” ni Olúwa wí.
Jeremiah 8:17 in English
Jeremiah 8:17 · Berean Standard Bible
“For behold, I will send snakes among you, vipers that cannot be charmed, and they will bite you,” declares the LORD.
Context
15Àwa ń retí àlàáfíà
kò sí ìre kan,
tí ó wá ní ìgbà ìmúláradá
bí kò ṣe ìpayà nìkan. 16Ìró ìfọn imú ẹṣin àwọn ọlọ̀tẹ̀
là ń gbọ́ láti Dani,
yíyan àwọn akọ ẹṣin
mú gbogbo ilẹ̀ wárìrì.
Wọ́n wá láti pa ilẹ̀ náà run,
gbogbo ohun tó wà níbẹ̀,
ìlú náà àti gbogbo olùgbé ibẹ̀. 17“Wò ó, èmi yóò rán àwọn ejò olóró sí àárín yín,
paramọ́lẹ̀ tí ẹ kò lè pa oró wọn,
yóò sì bù yín jẹ,”
ni Olúwa wí. 18Olùtùnú mi, nígbà tí ìbànújẹ́ ọkàn mi,
rẹ̀wẹ̀sì nínú mi. 19Fetí sí ẹkún àwọn ènìyàn mi
láti ilẹ̀ jíjìnnà wá:
“Olúwa kò ha sí ní Sioni bí?
Ọba rẹ̀ kò sí níbẹ̀ mọ́ ni?”
“Èéṣe tí wọ́n fi mú mi bínú pẹ̀lú ère wọn,
pẹ̀lú àwọn òrìṣà àjèjì tí wọn kò níláárí?”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.