Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọ́n sì ń wo ọgbẹ́ àwọn ènìyàn mi bí ẹni pé kò tó nǹkan. Wọ́n ń wí pé, ‘Àlàáfíà, Àlàáfíà,’ nígbà tí kò sì sí àlàáfíà.

Jeremiah 6:14 in English

Jeremiah 6:14 · Berean Standard Bible

They dress the wound of My people with very little care, saying, ‘Peace, peace,’ when there is no peace at all.

Context

12Ilé wọn o sì di ti ẹlòmíràn, oko wọn àti àwọn aya wọn, nígbà tí èmi bá na ọwọ́ mi sí àwọn olùgbé ilẹ̀ náà,” ni Olúwa wí. 13“Láti orí ẹni tí ó kéré sí orí ẹni tí ó tóbi ju, gbogbo wọn ni ó sì ní ojúkòkòrò fún èrè, àwọn wòlíì àti àlùfáà lápapọ̀ sì kún fún ẹ̀tàn. 14Wọ́n sì ń wo ọgbẹ́ àwọn ènìyàn mi bí ẹni pé kò tó nǹkan. Wọ́n ń wí pé, ‘Àlàáfíà, Àlàáfíà,’ nígbà tí kò sì sí àlàáfíà. 15Ojú ha a tì wọ́n nítorí ìwà ìríra wọn bí? Rárá, wọn kò ní ìtìjú mọ́, wọn kò tilẹ̀ ní oorun ìtìjú. Nítorí náà, wọn ó ṣubú láàrín àwọn tó ṣubú, a ó sì ké wọn lulẹ̀ nígbà tí mo bá bẹ̀ wọ́n wò,” ni Olúwa wí. 16Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Ẹ dúró sí ìkóríta, kí ẹ sì wò, ẹ béèrè fún ọ̀nà àtijọ́, ẹ béèrè ọ̀nà dáradára nì, kí ẹ rìn nínú rẹ, ẹ̀yin yóò sì rí ìsinmi fún ọkàn yín. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wí pé, ‘Àwa kì yóò rìn nínú rẹ̀.’

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.