Jeremiah 6:12
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ilé wọn o sì di ti ẹlòmíràn, oko wọn àti àwọn aya wọn, nígbà tí èmi bá na ọwọ́ mi sí àwọn olùgbé ilẹ̀ náà,” ni Olúwa wí.
Jeremiah 6:12 in English
Jeremiah 6:12 · Berean Standard Bible
Their houses will be turned over to others, their fields and wives as well, for I will stretch out My hand against the inhabitants of the land,” declares the LORD.
Context
10Ta ni ẹni tí mo lè bá sọ̀rọ̀ àti tí mo lè fún ní ìmọ̀ràn?
Ta ni yóò tẹ́tí sílẹ̀ sí mi?
Etí wọn ti di,
nítorí náà wọn kò lè gbọ́.
Ọ̀rọ̀ Olúwa, jẹ́ ohun búburú sí wọn,
wọn kò sì ní inú dídùn nínú rẹ̀. 11Èmi kún fún ìbínú Olúwa,
èmi kò sì le è pa á mọ́ra.
“Tú u sí orí àwọn ọmọ ńigboro,
àti sórí àwọn ọmọkùnrin tí wọn kó ra wọn jọ pọ̀,
àti ọkọ àti aya ni a ò mú sínú rẹ̀,
àti àwọn arúgbó tí ó ní ọjọ́ kíkún lórí. 12Ilé wọn o sì di ti ẹlòmíràn,
oko wọn àti àwọn aya wọn,
nígbà tí èmi bá na ọwọ́ mi
sí àwọn olùgbé ilẹ̀ náà,”
ni Olúwa wí. 13“Láti orí ẹni tí ó kéré sí orí ẹni tí ó tóbi ju,
gbogbo wọn ni ó sì ní ojúkòkòrò fún èrè,
àwọn wòlíì àti àlùfáà lápapọ̀
sì kún fún ẹ̀tàn. 14Wọ́n sì ń wo ọgbẹ́ àwọn ènìyàn
mi bí ẹni pé kò tó nǹkan.
Wọ́n ń wí pé, ‘Àlàáfíà, Àlàáfíà,’
nígbà tí kò sì sí àlàáfíà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.