Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ta ni ẹni tí mo lè bá sọ̀rọ̀ àti tí mo lè fún ní ìmọ̀ràn? Ta ni yóò tẹ́tí sílẹ̀ sí mi? Etí wọn ti di, nítorí náà wọn kò lè gbọ́. Ọ̀rọ̀ Olúwa, jẹ́ ohun búburú sí wọn, wọn kò sì ní inú dídùn nínú rẹ̀.

Jeremiah 6:10 in English

Jeremiah 6:10 · Berean Standard Bible

To whom can I give this warning? Who will listen to me? Look, their ears are closed,* so they cannot hear. See, the word of the LORD has become offensive to them; they find no pleasure in it.

Context

8Ìwọ Jerusalẹmu, gba ìkìlọ̀, kí Èmi kí ó má ba à lọ kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ, kí n sì sọ ilẹ̀ rẹ di ahoro, tí kò ní ní olùgbé.” 9Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Jẹ́ kí wọn pèsè ìyókù Israẹli ní tónítóní bí àjàrà; na ọwọ́ rẹ sí àwọn ẹ̀ka nì lẹ́ẹ̀kan sí i gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan ti í kó èso àjàrà jọ.” 10Ta ni ẹni tí mo lè bá sọ̀rọ̀ àti tí mo lè fún ní ìmọ̀ràn? Ta ni yóò tẹ́tí sílẹ̀ sí mi? Etí wọn ti di, nítorí náà wọn kò lè gbọ́. Ọ̀rọ̀ Olúwa, jẹ́ ohun búburú sí wọn, wọn kò sì ní inú dídùn nínú rẹ̀. 11Èmi kún fún ìbínú Olúwa, èmi kò sì le è pa á mọ́ra. “Tú u sí orí àwọn ọmọ ńigboro, àti sórí àwọn ọmọkùnrin tí wọn kó ra wọn jọ pọ̀, àti ọkọ àti aya ni a ò mú sínú rẹ̀, àti àwọn arúgbó tí ó ní ọjọ́ kíkún lórí. 12Ilé wọn o sì di ti ẹlòmíràn, oko wọn àti àwọn aya wọn, nígbà tí èmi bá na ọwọ́ mi sí àwọn olùgbé ilẹ̀ náà,” ni Olúwa wí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.