Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ojú ha a tì wọ́n nítorí ìwà ìríra wọn bí? Rárá, wọn kò ní ìtìjú mọ́, wọn kò tilẹ̀ ní oorun ìtìjú. Nítorí náà, wọn ó ṣubú láàrín àwọn tó ṣubú, a ó sì ké wọn lulẹ̀ nígbà tí mo bá bẹ̀ wọ́n wò,” ni Olúwa wí.

Jeremiah 6:15 in English

Jeremiah 6:15 · Berean Standard Bible

Are they ashamed of the abomination they have committed? No, they have no shame at all; they do not even know how to blush. So they will fall among the fallen; when I punish them, they will collapse,” says the LORD.

Context

13“Láti orí ẹni tí ó kéré sí orí ẹni tí ó tóbi ju, gbogbo wọn ni ó sì ní ojúkòkòrò fún èrè, àwọn wòlíì àti àlùfáà lápapọ̀ sì kún fún ẹ̀tàn. 14Wọ́n sì ń wo ọgbẹ́ àwọn ènìyàn mi bí ẹni pé kò tó nǹkan. Wọ́n ń wí pé, ‘Àlàáfíà, Àlàáfíà,’ nígbà tí kò sì sí àlàáfíà. 15Ojú ha a tì wọ́n nítorí ìwà ìríra wọn bí? Rárá, wọn kò ní ìtìjú mọ́, wọn kò tilẹ̀ ní oorun ìtìjú. Nítorí náà, wọn ó ṣubú láàrín àwọn tó ṣubú, a ó sì ké wọn lulẹ̀ nígbà tí mo bá bẹ̀ wọ́n wò,” ni Olúwa wí. 16Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Ẹ dúró sí ìkóríta, kí ẹ sì wò, ẹ béèrè fún ọ̀nà àtijọ́, ẹ béèrè ọ̀nà dáradára nì, kí ẹ rìn nínú rẹ, ẹ̀yin yóò sì rí ìsinmi fún ọkàn yín. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wí pé, ‘Àwa kì yóò rìn nínú rẹ̀.’ 17Èmi yan olùṣọ́ fún un yín, mo sì wí pé: ‘Tẹ́tí sí dídún fèrè náà,’ ẹ̀yìn wí pé, ‘Àwa kì yóò tẹ́tí sílẹ̀.’

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.