Jeremiah 51:37
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Babeli yóò parun pátápátá, yóò sì di ihò àwọn akátá, ohun ẹ̀rù àti àbùkù, ibi tí ènìyàn kò gbé.
Jeremiah 51:37 in English
Jeremiah 51:37 · Berean Standard Bible
Babylon will become a heap of rubble, a haunt for jackals,* an object of horror and scorn, without inhabitant.
Context
35Kí gbogbo ìparun tí ó ṣe sí ẹran-ara wa wà lórí Babeli,”
èyí tí àwọn ibùgbé Sioni wí.
“Kí ẹ̀jẹ̀ wa wà lórí gbogbo àwọn tí ń gbé Babeli,”
ni Jerusalẹmu wí. 36Nítorí náà, báyìí ni Olúwa wí:
“Wò ó, èmi yóò tì ọ́ lẹ́yìn lórí
ohun tí o fẹ́ ṣe. Èmi ó sì gbẹ̀san,
èmi yóò mú kí omi Òkun rẹ̀ àti orísun omi rẹ̀ gbẹ. 37Babeli yóò parun pátápátá,
yóò sì di ihò àwọn akátá,
ohun ẹ̀rù àti àbùkù, ibi tí ènìyàn kò gbé. 38Àwọn ènìyàn inú rẹ̀ bú ramúramù
bí ọmọ kìnnìún. 39Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkàn wọn bá ru sókè,
èmi yóò ṣe àsè fún wọn,
èmi yóò jẹ́ kí wọn mutí yó
tí wọn yóò máa kọ fun ẹ̀rín,
lẹ́yìn náà, wọn yóò sun oorun, wọn kì yóò jí,”
ni Olúwa wí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.