Jeremiah 51:39
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkàn wọn bá ru sókè, èmi yóò ṣe àsè fún wọn, èmi yóò jẹ́ kí wọn mutí yó tí wọn yóò máa kọ fun ẹ̀rín, lẹ́yìn náà, wọn yóò sun oorun, wọn kì yóò jí,” ni Olúwa wí.
Jeremiah 51:39 in English
Jeremiah 51:39 · Berean Standard Bible
While they are flushed with heat, I will serve them a feast, and I will make them drunk so that they may revel; then they will fall asleep forever and never wake up, declares the LORD.
Context
37Babeli yóò parun pátápátá,
yóò sì di ihò àwọn akátá,
ohun ẹ̀rù àti àbùkù, ibi tí ènìyàn kò gbé. 38Àwọn ènìyàn inú rẹ̀ bú ramúramù
bí ọmọ kìnnìún. 39Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkàn wọn bá ru sókè,
èmi yóò ṣe àsè fún wọn,
èmi yóò jẹ́ kí wọn mutí yó
tí wọn yóò máa kọ fun ẹ̀rín,
lẹ́yìn náà, wọn yóò sun oorun, wọn kì yóò jí,”
ni Olúwa wí. 40“Èmi yóò fà wọ́n lọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́-àgùntàn
tí a fẹ́ pa, gẹ́gẹ́ bí àgbò àti ewúrẹ́. 41“Báwo ni Ṣeṣaki yóò ṣe dí mímú, ìfọ́nnu gbogbo àgbáyé.
Irú ìpayà wo ni yóò bá
Babeli láàrín àwọn orílẹ̀-èdè!
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.