Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kí gbogbo ìparun tí ó ṣe sí ẹran-ara wa wà lórí Babeli,” èyí tí àwọn ibùgbé Sioni wí. “Kí ẹ̀jẹ̀ wa wà lórí gbogbo àwọn tí ń gbé Babeli,” ni Jerusalẹmu wí.

Jeremiah 51:35 in English

Jeremiah 51:35 · Berean Standard Bible

May the violence done to me and to my flesh be upon Babylon,” says the dweller of Zion. “May my blood be on the dwellers of Chaldea,” says Jerusalem.

Context

33Ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run àwọn ọmọ Israẹli sọ nìyìí: “Ọmọbìnrin Babeli dàbí ìpakà àsìkò láti kórè rẹ̀ kò ní pẹ́ dé mọ́.” 34“Nebukadnessari ọba Babeli tó jẹ wá run, ó ti mú kí ìdààmú bá wa, ó ti sọ wá di àgbá òfìfo. Gẹ́gẹ́ bí ejò, ó ti gbé wa mì. Ó fi oúnjẹ àdídùn wa kún inú rẹ̀, lẹ́yìn náà ni ó pọ̀ wá jáde. 35Kí gbogbo ìparun tí ó ṣe sí ẹran-ara wa wà lórí Babeli,” èyí tí àwọn ibùgbé Sioni wí. “Kí ẹ̀jẹ̀ wa wà lórí gbogbo àwọn tí ń gbé Babeli,” ni Jerusalẹmu wí. 36Nítorí náà, báyìí ni Olúwa wí: “Wò ó, èmi yóò tì ọ́ lẹ́yìn lórí ohun tí o fẹ́ ṣe. Èmi ó sì gbẹ̀san, èmi yóò mú kí omi Òkun rẹ̀ àti orísun omi rẹ̀ gbẹ. 37Babeli yóò parun pátápátá, yóò sì di ihò àwọn akátá, ohun ẹ̀rù àti àbùkù, ibi tí ènìyàn kò gbé.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.