Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run àwọn ọmọ Israẹli sọ nìyìí: “Ọmọbìnrin Babeli dàbí ìpakà àsìkò láti kórè rẹ̀ kò ní pẹ́ dé mọ́.”

Jeremiah 51:33 in English

Jeremiah 51:33 · Berean Standard Bible

For this is what the LORD of Hosts, the God of Israel, says: “The Daughter of Babylon is like a threshing floor at the time it is trampled. In just a little while her harvest time will come.”

Context

31Ìránṣẹ́ kan ń tẹ̀lé òmíràn láti sọ fún ọba Babeli pé gbogbo ìlú rẹ̀ ni a ti kó ní ìgbèkùn. 32Odò tí ó sàn kọjá kò sàn mọ́ ilẹ̀ àbàtà gbiná, àwọn jagunjagun sì wárìrì.” 33Ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run àwọn ọmọ Israẹli sọ nìyìí: “Ọmọbìnrin Babeli dàbí ìpakà àsìkò láti kórè rẹ̀ kò ní pẹ́ dé mọ́.” 34“Nebukadnessari ọba Babeli tó jẹ wá run, ó ti mú kí ìdààmú bá wa, ó ti sọ wá di àgbá òfìfo. Gẹ́gẹ́ bí ejò, ó ti gbé wa mì. Ó fi oúnjẹ àdídùn wa kún inú rẹ̀, lẹ́yìn náà ni ó pọ̀ wá jáde. 35Kí gbogbo ìparun tí ó ṣe sí ẹran-ara wa wà lórí Babeli,” èyí tí àwọn ibùgbé Sioni wí. “Kí ẹ̀jẹ̀ wa wà lórí gbogbo àwọn tí ń gbé Babeli,” ni Jerusalẹmu wí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.