Jeremiah 51:32
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Odò tí ó sàn kọjá kò sàn mọ́ ilẹ̀ àbàtà gbiná, àwọn jagunjagun sì wárìrì.”
Jeremiah 51:32 in English
Jeremiah 51:32 · Berean Standard Bible
The fords have been seized, the marshes set on fire, and the soldiers are terrified.”
Context
30Gbogbo àwọn jagunjagun
Babeli tó dáwọ́ ìjà dúró sínú àgọ́ wọn.
Agbára wọn ti tán, wọ́n ti dàbí obìnrin.
Ibùgbé rẹ̀ ni a ti dáná sun,
gbogbo irin ẹnu-ọ̀nà wọn ti di fífọ́. 31Ìránṣẹ́ kan ń tẹ̀lé òmíràn
láti sọ fún ọba Babeli pé
gbogbo ìlú rẹ̀ ni a ti kó ní ìgbèkùn. 32Odò tí ó sàn kọjá kò sàn mọ́
ilẹ̀ àbàtà gbiná, àwọn jagunjagun sì wárìrì.” 33Ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run àwọn ọmọ Israẹli sọ nìyìí:
“Ọmọbìnrin Babeli dàbí ìpakà àsìkò láti kórè rẹ̀ kò ní pẹ́ dé mọ́.” 34“Nebukadnessari ọba Babeli tó jẹ wá run,
ó ti mú kí ìdààmú bá wa,
ó ti sọ wá di àgbá òfìfo.
Gẹ́gẹ́ bí ejò, ó ti gbé wa mì.
Ó fi oúnjẹ àdídùn wa kún inú rẹ̀,
lẹ́yìn náà ni ó pọ̀ wá jáde.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.