Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Gbogbo àwọn jagunjagun Babeli tó dáwọ́ ìjà dúró sínú àgọ́ wọn. Agbára wọn ti tán, wọ́n ti dàbí obìnrin. Ibùgbé rẹ̀ ni a ti dáná sun, gbogbo irin ẹnu-ọ̀nà wọn ti di fífọ́.

Jeremiah 51:30 in English

Jeremiah 51:30 · Berean Standard Bible

The warriors of Babylon have stopped fighting; they sit in their strongholds. Their strength is exhausted; they have become like women. Babylon’s homes have been set ablaze, the bars of her gates are broken.

Context

28Sọ àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú àwọn ọba Media di mímọ́ sórí rẹ̀, àwọn baálẹ̀ rẹ̀, àti gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀, àti gbogbo orílẹ̀-èdè tí wọ́n jẹ ọba lé lórí. 29Ilẹ̀ wárìrì síyìn-ín sọ́hùn-ún, nítorí pé ète Olúwa, sí Babeli dúró, láti ba ilẹ̀ Babeli jẹ́ lọ́nà tí ẹnikẹ́ni kò ní lè gbé inú rẹ̀ mọ́. 30Gbogbo àwọn jagunjagun Babeli tó dáwọ́ ìjà dúró sínú àgọ́ wọn. Agbára wọn ti tán, wọ́n ti dàbí obìnrin. Ibùgbé rẹ̀ ni a ti dáná sun, gbogbo irin ẹnu-ọ̀nà wọn ti di fífọ́. 31Ìránṣẹ́ kan ń tẹ̀lé òmíràn láti sọ fún ọba Babeli pé gbogbo ìlú rẹ̀ ni a ti kó ní ìgbèkùn. 32Odò tí ó sàn kọjá kò sàn mọ́ ilẹ̀ àbàtà gbiná, àwọn jagunjagun sì wárìrì.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.