Jeremiah 51:28
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Sọ àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú àwọn ọba Media di mímọ́ sórí rẹ̀, àwọn baálẹ̀ rẹ̀, àti gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀, àti gbogbo orílẹ̀-èdè tí wọ́n jẹ ọba lé lórí.
Jeremiah 51:28 in English
Jeremiah 51:28 · Berean Standard Bible
Prepare the nations for battle against her— the kings of the Medes, their governors and all their officials, and all the lands they rule.
Context
26A kò ní mú òkúta kankan láti
ọ̀dọ̀ rẹ̀ lò gẹ́gẹ́ bí igun ilé tàbí
fún ìpínlẹ̀ nítorí pé ìwọ yóò di
ahoro títí ayé,”
ní Olúwa wí. 27“Gbé àsíá sókè ní ilẹ̀ náà!
Fọn ìpè láàrín àwọn orílẹ̀-èdè!
Sọ àwọn orílẹ̀-èdè di mímọ́ sórí rẹ̀,
pe àwọn ìjọba yìí láti dojúkọ ọ́:
Ararati, Minini àti Aṣkenasi.
Yan olùdarí ogun láti kọlù ú,
rán àwọn ẹṣin sí i bí ọ̀pọ̀ eṣú. 28Sọ àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú àwọn ọba Media di mímọ́ sórí rẹ̀,
àwọn baálẹ̀ rẹ̀, àti gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀,
àti gbogbo orílẹ̀-èdè tí wọ́n jẹ ọba lé lórí. 29Ilẹ̀ wárìrì síyìn-ín sọ́hùn-ún,
nítorí pé ète Olúwa, sí Babeli dúró,
láti ba ilẹ̀ Babeli jẹ́ lọ́nà
tí ẹnikẹ́ni kò ní lè gbé inú rẹ̀ mọ́. 30Gbogbo àwọn jagunjagun
Babeli tó dáwọ́ ìjà dúró sínú àgọ́ wọn.
Agbára wọn ti tán, wọ́n ti dàbí obìnrin.
Ibùgbé rẹ̀ ni a ti dáná sun,
gbogbo irin ẹnu-ọ̀nà wọn ti di fífọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.